1. JESU alail’ abawon,
O ti f’ eje Re ra mi,
Nko nani ohunkohun,
Lehin agbelebu Re.
2. Tire nikan ni mo je,
O fun mi l’ ekun ayo,
Lati isisiyi lo
Iyin Re ni ngo ma wa.
3. Je ki ngbe itiju Re,
Ki njewo oruko Re,
Ki nwa lati tele O,
Bi mo tile nri egan.
4. ‘Gbat’ O ba yo n’nu ogo,
Ti mo de ile l’ oke,
Ahon mi yio kigbe pe,
Tire nikan ni mo je.
(Visited 287 times, 1 visits today)