YBH 346

AO sise ! ao sise! Om’ -Olorun ni wa

1. AO sise ! ao sise! Om’ -Olorun ni wa,
Jek’ a tele ona ti Oluwa wa to;
K’ a f’ imoran Re so agbara wa d’ otun,
K’ a fi gbogbo okun wa sise t’ a o se.
Foriti ! Foriti !
Foriti ! Foriti !
K’ a reti, k’ a s’ ona
Titi Oluwa yio fi de.

2. Ao sise ! ao sise ! bo awon t’ ebi npa,
Ko awon alare lo s’ orisun iye !
Ninu agbalebu l’ awa o ma s’ ogo,
Nigbat’ a ba nkede pe, ” Ofe n’ igbala,”

3. Ao sise ! ao sise ! gbogbo wa ni yio se,
Ijoba okunkun at’iro yio fo,
Ao si gbe oruko Jehofah leke, won,
Ninu orin iyin wa pe, “Ofe n’ igbala,”

4. Ao sise ! ao sise ! I’ agbara Oluwa,
Agbada at’ ade yio si je ere wa;
Ile awon oloto yio si je ti wa,
Gbogbo wa o jo ho pe, “Ofe n’ igbala,”

(Visited 3,675 times, 7 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you