1. AJAGUN Jesu l’ emi bi,
At’ omo ehin Re?
Ngo ha beru lati wasu
Agbara isin Re?
2. Ao ha gbe mi g’ oke orun
Lori ‘busun ‘rorun,
Gbati opo ja f’ ere na
Lori okun eje?
3. Ko ha s’ ota lati ba ja?
Ti mo ni lati ko?
Aiye ha ba or’-ofe t’y’o
Mu mi d’ oro Re je?
4. Mo ni ja bi ngo ba joba;
Oluwa, pelu mi;
Ngo f’ ara da gbogbo ise,
Pelu iranwo Re.
5. B’ awon enia Re tile ku,
Nwon o segun ‘ja na,
Nwon ri isegun l’ okere,
Eru ko sib a won.
6. Gb’ ojo t’ o l’ ogo nib a de,
T’ awon ogun Re ndan;
Ninu aso ‘segun l’ oke,
Ogo yio je Tire.
(Visited 669 times, 1 visits today)