YBH 349

MA so ra, okan mi

1. MA so ra, okan mi,
A won ota dide;
Ogun ese si mura tan,
Lati fa o lu ‘le.

2. Ma ja, ma gbadura,
Mase so ‘reti nu;
Bere l’ otun l’ ojojumo,
Tor’ agbara l’ oke.

3. Ma ro p’ o ti segun,
Ma si se tu ‘ra ‘le,
Ise re ki o pin titi
Iwo o fi gb’ ade.

4. Ma ja lo, okan mi,
Tit’ iku y’o fi de;
Olorun yio mu o lo ‘le
Gb’ emi re ba pinya.

(Visited 533 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you