1. JESU Or’ elese mo de,
Em’ otosi wa fun ‘rawo,
Ara mi su mi fun ese,
Na apa Re gba mi s’ ile.
2. S’ anu ko gb’ okan ti nsegbe,
‘Wo nikan lo le wo mi sa,
D’ aworan Re si mi l’ okan,
Jo gba mi ki n’ ma ba segbe.
3. Mo mo pee mi ko le se,
Ara mi ye fun ife Re,
Mo f’ ara mi gbogbo fun O,
‘Tori ‘wo lo le sise na.
(Visited 215 times, 1 visits today)