YBH 42

OLORUN awa fe

1. OLORUN awa fe,
Ile t’ ola Re wa;
Ayo ibugbe Re
Ju gbogbo ayo lo.

2. Ile adura ni,
Fun awon omo Re
Jesu si wa nibe,
Lati gbo ebe won.

3. Awa fe ase Re,
Ti nte okan l’ orun
Iwo l’ onje iye,
Ti onigbagbo nje.

4. Awa fe oro Re,
Oro alafia
T’ itunu at ‘iye
Oro ayo titi.

5. Awa fe orin Re,
Ti a nko l’ aiye yi;
Sugbon awa fe mo,
Orin ayo t’ orun.

6. Jesu Oluwa wa,
Busi ‘fe wa nihin;
Mu wa de ‘nu ogo,
Lati yin O titi.

(Visited 3,003 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you