1. OLORUN orile-ede,
Lat’ ibugbe Re l’ oke,
Gbo ebe awon enia Re,
K’ O dide si ‘gbala won.
2. Bi ese t’ o b’ okan wa je,
Nf’ ohun rara ke f’ esan;
Iwo l’ anu t’ o ju be lo,
Eje Jesu le we won.
3. Jek’ ife bo ‘rekoja wa,
K’ eje na fo ebi wa,
Gba enia Re l’ owo ise,
Ma je k’ ile Re baje.
4. A pada pelu ironu,
A wole ni ese Re,
A ngbadura, a si nsofo,
Gbo ti wa, k’ O si gba wa.
(Visited 326 times, 1 visits today)