YBH 469

ORISUN lai, t’ ayo gbogbo

1. ORISUN lai, t’ ayo gbogbo,
Ki iyin Re gba enu wa,
Nigbat’ a wa sinu ‘le Re,
‘Wo-t’ ore Re buk’ odun wa.

2. Bi aiye yi ti tobi to,
Owo Re l’ od’ opo re mu
‘Wo l’ o ko orun lati ran,
L’ o ko okunkun lati su.

3. Itana yo li ase Re,
Ododo se ile l’ oso,
Orun si san l’ akoko re,
Lati m’ ohun ogbin dagba.

4. L’ akoko ‘kore owo Re
Tu onje ka s’ ile gbogbo,
Otutu ko si n’ ipa kan
Nigbati itoju Re wa.

5. Jek’ a f’ ayo sin Olorun,
L’ owuro ati l’ asale,
Orin ayo ye fun ojo,
Ose, osu ati odun.

(Visited 540 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you