1. YIN Olorun Oba wa;
E gbe ohun iyin ga;
Anu Re o wa titi,
L’ ododo dajudaju.
2. Yin Enit’ oda, orun
Ti o nran l’ojojumo;
Anu Re o wa titi,
L’ododo dajudaju.
3. Ati osupa l’oru
Ti o ntan ‘mole jeje;
Anu Re o wa titi,
L’ododo dajudaju.
4. Yin Enit’ o nm’ ojo ro,
T’ O nmu irugbin dagba;
Anu Re o wa titi,
L’ododo dajudaju.
5. Enit’ O pase fun ‘le
Lati mu eso po si;
Anu Re o wa titi,
L’ododo dajudaju.
6. Yin fun ikore oko,
O mu ki aka wa kun;
Anu Re o wa titi,
L’ododo dajudaju.
Stanza 7 of Hymn 470
Yin f’onje t’ o ju yi lo,
Eri ‘bukun ailopin;
Anu Re o wa titi,
L’ododo dajudaju.
Stanza 8 of Hymn 470
Ogo f’ Oba olore:
Ki gbogbo eda gberin:
Ogo fun Baba, Omo,
At’ Emi: Metalokan.
(Visited 1,669 times, 5 visits today)