1. GB’ ope mi, Oluwa,
Lat’ okan l’ o ti wa,
Iwo t’ O gba die opo,
K’yo kegan ‘more mi.
2. Tire ‘ eran gbogbo,
Ti nfo lori oke;
Gbogbo ‘sura t’ o wa l’ odo,
At’ oro ‘nu ile.
3. Kini ‘ba damu Re?
Kil’ O fe ti ko si?
Apakan ohun t’ O fun mi
Ko mo mu wa fun O?
4. Ohun idupe ko
L’ O fe, bi okan wa;
Ko s’ ohun t’ o te O lorun
Bi okan imore.
5. Eyi ni mo mu wa, –
Okan t’ o kun fu je ‘fe,
O n’ iyi l’ oju Re j’ opo
Ore ode okan.
(Visited 2,708 times, 1 visits today)