1. AWA nbebe fun ‘le wa,
Ki Afrika ko pe;
K’ Olorun Olodumare,
Fi alafia fun u.
2. Ibukun f’ awon to fe,
Irora n’nu odi re,
At’ ayo f’ awon oba re,
At’ enia re gbogbo.
3. Fun gbogb’ awon omo re,
T’o nja fun ire re,
L’ agbara, ogbon, suru,
K’ ise won ma jasan.
4. Ki gbogbo omo Afrik,
F’ ohun kan ke pe O;
F’ omnira ‘le Baba won,
F’ alafia Iran won.
5. Jehova Baba jowo,
Iwo l’ a gbekele’
F’ anu dahun adura wa,
Eleda gbogb’ aiye.
(Visited 429 times, 1 visits today)