YBH 474

OLUWA wa, a nkorin ti

1. OLUWA wa, a nkorin ti
Owo nla t’ o mu wa duro;
Odun titun f’ anu Re han,
Jek’ anu pelu re d’ opin.

2. L’ osan l’ oru, n’ ile, l’ ayo,
Oluwa wa l’ o ntoju wa;
O si nf’ opo onje bo wa,
O si nf’ liana Re to wa.

3. A s’ ope fun ‘yi t’ o koja;
Eyiti mbo – awa ko mo;
A fi le iso Re l’ owo,
A si simi n’ iwaju Re.

4. Ninu ire tabi ibi,
Ma j’ ayo at’ isimi wa;
Ao f’ ireti fa ore Re,
Ao yin won n’nu ayid’ aiye.

5. Gba ‘ku ba f’ opin s’ orin wa,
T’ o si s’ ahon ese d’ odi;
Olorun ti a gbekele,
Yio m’ okan way o ni orun.

(Visited 368 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you