1. AO ha pade l’ eti odo,
T’ ese angeli ti te,
‘T o mo gara bi kristali,
Leba ite Olorun?
Ao ha pade l’ eti odo,
Odo didan, odo didan na,
Pel’ awon mimo leb’ odo,
T’ o nsan leba ite na?
2. L’ eti bebe odo na yi,
Pel’ Olus’-agutan wa,
A o ma rin, a o sin,
B’ a ti ntele ‘pase Re.
3. K’ a to de odo didan na,
A o s’ eru wa kale;
Jesu yio gba eru ese
Awon ti yio de l’ ade.
4. Nje leba odo tutu na,
Ao r’ oju Olugbala;
Emi wa ki o pinya mo,
Yio korin ogo Re.
(Visited 5,232 times, 6 visits today)