YBH 489

NIHIN l’ awa nje ‘rora

1. NIHIN l’ awa nje ‘rora,
Nihin ni a ma pinya,
L’ orun ko si ‘pinya,
A! bi yio ti dun to!
Dun to, dun to, dun to!
A! bi yio ti dun to!
Gbat’ a ki yio pinya mo.

2. Awon t’ o feran Jesu,
Nwon o lo s’ oke orun,
Lo b’ awon t’ o ti lo.

3. Omode yio wa nibe,
T’ o wa Olorun l’ aiye,
Ni gbogbo ‘le eko.

4. Oluko, baba, iya,
Nwon o pade nibe na,
Nwon ki yio pinya mo.

5. Bi a to ti yo po to!
Gbat’ a ba r’ Olugbala,
Li ori ite Re!

6. Nibe l’ ao korin ayo,
Titi aiye ailopin,
L’ a o ma yin Jesu.

(Visited 617 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you