YBH 526

ILE ewa wonni, b’ o ti dara to

1. ILE ewa wonni, b’ o ti dara to!
Ibugbe Olorun, t’ oju ko ti ri;
Tal’ o fe ibe, lehin aiye yi?
Tal’ o fe k’ a wo on ni aso funfun?

2. Awon wonni, t’ o ji ninu orun won;
Awon t’ o n’ igbagbo si nkan t’ a ko ri;
Awon t’ o k’ aniyan won l’ Olugbala,
Awon ti ko tiju agbelebu Krist’.

3. won ti ko nani gbogbo nkan aiye,
Awon t’ o le s’ oto de oju iku,
Awon t’ o nrubo ife l’ ojojumo,
Awon t’ a f’ igbala Jesu ra pada.

4. Itiju ni fun nyin, Om’-ogun Jesu,
Enyin ara ilu ibugbe orun,
Kinla! E nfi fere at’ ilu sire,
‘Gbat’ O ni k’ e sise, t’ O sip e, “E ja?”

5. B’ igbi omi aiye si ti nkolu wa,
Jesu, Oba-Ogo, so si wa l’ eti
Adun t’o wa l’orun, ilu mimo ni
Nibit’ isimi wa lai ati lailai

(Visited 1,850 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you