YBH 525

JERUSALEM t’ orun

1. JERUSALEM t’ orun,
Orin mi, ilu mi!
Ile mi bi mba ku,
Ekun ibukun mi;
Ibi ayo!
Nigbawo ni,
Ngo r’ oju re,
Olorun mi?

2. Odi re, ilu mi,
L’ a fi pearl se l’ oso;
‘Lekun re ndan fun ‘yin,
Wura ni ita re!

3. Orun ki ran nibe,
Beni ko s’ osupa;
A ko wa iwonyi,
Kristi n’ imole ibe.

4. Nibe l’ Oba mi wa,
T’ a da l’ ebi l’ aiye,
Angeli nkorin fun,
Nwon si nteriba fun.

5. Patriak’ igbani,
Par’ ayo won nibe;
Awon woli, nwon now
Omo Alade won.

6. Nibe ni mo le ri
Awon apostili,
At’ awon akorin
Ti nlu harpu wura.

7. Ni agbala wonni,
Ni awon martir’ wa;
Nwon wo aso ala,
Ogo bo ogbe won.

8. T’ emi yi sa su mi,
Ti mo ngb’ ago kedar!
Ko si ‘ru yi l’ oke,
Nibe ni mo fe lo.

(Visited 13,333 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you