1. LEHIN odun die,
Lehin igba die,
A o ko wa jo pel’ awon
Ti o sun n’ iboji.
Jesu Oluwa mi!
Mu mi mura de O;
Jo we mi ninu eje Re,
Si ko ese mi lo.
2. Lehin ojo die
L’ aiye buburu yi,
A o de b’ orun ko si mo,
Ile daradara.
3. Lehin ‘yonu die,
Lehin ‘pinya die,
Lehin ekun ati aro
Aki y’o sokun mo’
4. Ojo ‘simi die
L’ a ni tun ri l’ aiye;
Awa o de ib’ isimi
Ti ki y’o pin lailai.
5.Ojo die l’ o ku,
On y’o tun pada wa;
Enit’ o ku k’ awa le ye,
K’ a ba le ba joba.
(Visited 1,127 times, 1 visits today)