YBH 523

JERUSALEM ibi ayo

1. JERUSALEM ibi ayo,
T’ o se owon fun mi;
‘Gbawo n’ ise mi yio pari,
L’ ayo, l’ alafia?

2. ‘Gbawo ni oju mi yio ri
Enu-bode pearl re?
Odi re to de fun ‘gbala,
Ita wura didan.

3. ‘Gbawo, ilu Olorun mi,
L’ emi o d’ afin re?
Nibiti ijo ki tuka,
Nib’ ayo ailopin.

4. Ese t’ emi o ko iya,
Iku at’ iponju?
Mo now ile rere Kenaan,
Ile ‘mole titi.

5. Apostili, martir’, woli,
Nwon y’ Olugbala ka;
Awa tikarawa fere
Dapo mo ogun na.

6. Jerusalem ilu ayo,
Okan mi nfa si o;
‘Gbati mo ba ri ayo re,
Ise mi y’o pari.

(Visited 1,098 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you