1. NIHIN mo j’ alejo,
Orun n’ ile.
Aginju l’ aiye yi,
Orun n’ ile.
Ewu on ‘banuje
Wa yi mi kakiri;
Orun ni ilu mi,
Orun n’ ile.
2. Bi iji tile nja,
Orun n’ ile.
Kukuru l’ ajo mi,
Orun n’ ile.
Iji lile ti nja
Fe rekoja lo na;
Ngo sa de ‘le mi sa;
Orun n’ ile.
3. Lodo Olugbala,
Orun n’ ile.
A o se mi l’ ogo,
Orun n’ ile.
Awon mimo wa mbe
At’ awon ti mo fe;
Nibe ni ngo simi,
Orun n’ ile.
4. Nje nki y’o kun, ‘tori
Orun n’ ile.
Ohun t’ o wu ki nri,
Orun n’ ile.
Ngo sa duro dandan,
L’ otun Oluwa mi;
Orun ni ilu mi,
Orun n’ ile.
(Visited 3,029 times, 1 visits today)