1. ILE ayo kan wa
Ti o Jina,
Ti awon mimo wa;
Nwon nran b’ orun;
A! nwon nkorin didun,
Yiye l’ Olugbala wa,
Ki iyin Re ko ro,
Yin, yin lailai.
2. Wa s’ ile ayo na,
Wa, wa kalo;
E se nsiyemeji?
E se nduro?
A o wa l’ alafia,
Kuro l’ ese at’ aro,
A o ba O joba,
L’ ayo lailai.
3. Oju gbogbo won ndan
N’ ile ayo;
N’ ipamo Baba wa,
Ife ki ku.
Nje sure lo s’ ogo,
Gba ade at’ ijoba,
T’ o mo ju orun lo,
Joba titi.
(Visited 1,222 times, 1 visits today)