1. JEKI m’ n’ ipo mi lodo Re,
Jesu, Iwo isimi mi;
‘Gbana l’ okan mi y’o simi
Y’o si ri ekun ‘bukun gba.
2. Jeki m’ n’ ipo mi lodo Re,
K’ emi k’ o le ri ogo Re;
‘Gbana ni okan etan mi
Yio ri eni f’ ara le.
3. Jeki m’ n’ ipo mi lodo Re,
Nibi awon mimo nyin O,
‘Gbana ni okan ese mi,
Y’o dekun ese ni dida.
4. Jeki m’ n’ ipo mi lodo Re,
Nibi a ki y’ ipo pada,
Nib’ a ko npe “o digbose”
Titi aiye, titi aiye.
(Visited 463 times, 1 visits today)