YBH 530

A! NWON ti gun s’ ebute

1. A! NWON ti gun s’ ebute,
L’ oke orun; L’ oke orun;
Ebi ko ni pa won mo,
Nwon bo lowo irora,
L’ oke orun; L’ oke orun

2. A! nwon ko wa fitila,
L’ oke orun; L’ oke orun
‘Mole ni l’ ojo gbogbo,
Jesu si n’ Imole won,
L’ oke orun; L’ oke orun

4. A! wura n’ ita won je,
L’ oke orun; L’ oke orun
Ogo ‘be si po pupo;
Agbo Jesu ni nwon je
L’ oke orun; L’ oke orun

4. A! otutu ki mu mo
L’ oke orun; L’ oke orun
Owore won ti koja,
Gbogbo ojo l’ o dara,
L’ oke orun; L’ oke orun

5. A! nwon dekun ija ja,
L’ oke orun; L’ oke orun
Jesu l’ O ti gba won la,
T’ awon Tire l’ o si nrin,
L’ oke orun; L’ oke orun

6. A! nwon ko ni sokun mo,
L’ oke orun; L’ oke orun
Jesu saw a lodo won,
Lodo Re ni ayo wa,
L’ oke orun; L’ oke orun

7. A! a o dapo mo won,
L’ oke orun; L’ oke orun
A nreti akoko wa,
‘Gba Oluwa ba pe ni
S’ oke orun; L’ oke orun.

(Visited 1,629 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you