YBH 531

A! RO ti ibugbe orun

1. A! RO ti ibugbe orun,
Li eba odo imole,
Nibit’ awon mimo wa l’ aiku,
T’ a wo won li aso funfun.
Lok’ orun! Lok’ orun!
A! ro ti ibugbe orun!
Lok’ orun! Lok’ orun
A! ro ti ibugbe orun.

2. A! ro t’ awon ore nibe,
Awon ti o ti lo saju wa,
Ati awon orin tin won nko,
N’ ile won, l’ afin Olorun.

3. Olugbala mi wa nibe,
N’be l’ awon ‘batan mi nsimi,
Jeki nfi’ banuje s’ apakan,
Ki nfo lo ile abukun.

4. Mo fere de ibugbe na,
Nitori mo r’ opin ajo mi,
Opo awon ti okan mi fe,
Nwon ns’ ona, nwon nduro de mi.

(Visited 357 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you