1. GBAT’ aiye yi ba koja,
Ti orun re ba si wo,
Ti a ba wo ‘nu ogo,
T’ a bojuwo ehin wa;
‘Gbana, Oluwa, ngo mo
Bi ‘gbese mi ti po to.
2. ‘Gba mo ba de ‘b’ ite Re,
L’ ewa ti ki se t’ emi;
‘Gba mo ri O b’ O ti ri,
Ti mo fe O l’ afetan;
Gbana, Oluwa ngo mo
Bi ‘gbese mi ti po to.
3. ‘Gba mba ngbo orin orun,
Ti ndun bi ohun ara,
Bi iro omi pupo,
T’ o si ndun b’ ohun duru;
Gbana, Oluwa ngo mo
Bi ‘gbese mi ti po to.
4. Oluwa, jo, jek’ a ri
Ojiji Re l’ aiye yi;
K’ a mo adun ‘dariji
Pelu iranwo Emi;
Ki ntile mo l’ aiye yi
Die ninu ‘gbese mi.
5. Ore-ofe l’ o yan mi,
L’ o yo mi olugbala mi,
Jesu l’ olugbala mi,
Emi so mi di mimo;
Ko mi, ki nfi han l’ aiye
Bi ‘gbese mi ti po to.
(Visited 2,189 times, 1 visits today)