1. OJU ko ti ri, eti ko ti gbo
Ese t’ Olugbala pa f’ enia Re,
Awon ti O feran, tin won feran Re,
Ti nwon nfi ayo sin ninu ile Re.
2. B’ orun ti dun to, ko s’ eni le mo,
Ayo re ko ti la s’ okan eda,
Bi ijoba aiye ba l’ ewu to yi,
Bawo n’ ijoba Olorun yio ti ri?
3. Ilu ail’ ese ti ko si iku,
Nibiti a ki pe “odigbose,”
Ti ko si ipinya, ti ko si ekun,
Ibiti Jesu joba ti l’ ayo to!
4. Ipade pelu awon t’ o ti lo,
Baba t’ on t’ omo, oko t’ on t’ ya,
Ore at’ ojulumo t’ a ti saju,
A! b’ ijoba Olorun yio ti dun to!
5. Pelu awon mimo lati ma ko
Orin Mose ati Od-agutan;
Nibiti ko si aniyan fun ara,
Ti Jesu gbe nsike wa, yio ti dun to!
6. Ki npadanu aiye on oro re,
K’ ese mi le ilu ogo yi,
Nigba mo ba nrin ita wura l’ oke,
Ngo gbagbe gbogbo iya ti mo ti je.
(Visited 477 times, 1 visits today)