1. PARADISE! Paradise!
Tani ko fe simi?
Tani ko fe ‘le ayo na,
Ile alabukun;
Nib’ awon oloto
Wa lai ninu’ mole,
Nwon nyo nigbagbogbo,
Niwaju Olorun.
2. Paradise! Paradise!
Aiye ndarugbo lo;
Tani ko si fe lo simi,
Nib’ ife ki tutu?
3. Paradise! Paradise!
Aiye yi ma su mi!
Okan mi nfa s’ odo Jesu,
Emi nfe r’ oju Re;
4. Paradise! Paradise!
Mo fe ki nye d’ ese,
Mo fe ki nwa lodo Jesu,
Li ebute mimo.
5. Paradise! Paradise!
Nko ni duro pe mo:
Nisiyi b’ enipe mo ngbo
Ohun orin orun:
6. Jesu, Oba Paradise,
Pa mi mo n’nu ‘fe Re;
Mu mi de ile ayo na,
N’ibi ‘simi l’ oke.
(Visited 1,246 times, 1 visits today)