1. ASORO ile ‘bukun ni
Ile didan, at’ ile ewa
‘Gbagbogbon l’ a nso t’ogo re;
Y’o ti dun to lati de ‘be!
2. A ns’ oro ita wura re,
Oso odi re ti ko l’ egbe;
‘Faiji re ko se f’ enu so;
Y’o ti dun to lati de ‘be!
3. A nso p’ ese ko si nibe,
Ko s’ aniyan at’ ibanuje,
Pelu ‘danwo l’ ode, ninu;
Y’o ti dun to lati de ‘be!
4. Ti a ko le f’ orin aiye we,
B’ o ti wu k’ orin wa dun to,
Y’o ti dun to lati de ‘be!
5. A ns’ oro isin ife re,
Ti agbada t’ awon mimo now;
Ijo akobi ti oke;
Y’o ti dun to lati de ‘be!
6. Jo, Oluwa, t’ ibi, t’ ire,
Sa se emi wa ye fun orun,
Laipe, awa na yio mo
B’o ti dun to lati de be!
(Visited 12,533 times, 6 visits today)