YBH 537

OKE kan mbe jina rere

1. OKE kan mbe jina rere,
Lehin odi ilu,
Nibit’ a kan Oluwa mo,
Enit’ O ku fun wa.

2. A ko le mo, a ko le so,
B’ irora re ti lo,
Sugbon a mo pe ‘tori wa
L’ O se jiya nibe.

3. O ku k’ a le ri ‘dariji,
K’ a le huwa rere;
K’ a si d’ orun nikehin,
N’ itoye eje Re.

4. Ko tun s’ eni ‘re miran mo
T’ o le sanwo ese;
On l’ O le s’ ilekun orun,
K’ O si gba wa s’ ile.

5. A! b’ ife Re ti s’ owon to!
O ye k’ a feran Re!
K’ a si gbekele eje Re,
K’ a si se ife Re.

(Visited 482 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you