YBH 538

LAI lodo Oluwa

1. “LAI lodo Oluwa!”
Amin, beni k’o ri,
Iye wa ninu oro na,
Aiku ni titi lai,
Nihin ninu ara,
Mo sako jinna si;
Sibe alale ni mo nfi,
Ojo kan sunmole!

2. Ile Baba loke,
Ile okan mi ni;
Emi nfi oju igbagbo
Wo bode wura re!
Okan mi nfa pupo,
S’ ile na ti mo fe,
Ile didan t’ awon mimo
Jerusalem t’ orun.

3. Awosanma dide,
Gbogbo ero mi pin;
Bi adaba Noa, mo nfo
Larin iji lile.
Sugbon sanma kuro,
Iji si rekoja,
Ayo ati alafia
Si gba okan mi kan.

4. L’ oro ati l’ ale
L’ osan ati l’ oru,
Mo ngbo orin orun, bori
Rudurudu aiye,
Oro ajinde ni,
Hiho isegun ni,
Lekan si, “Lai lod’ Oluwa.”
Amin, beni ko ri.

(Visited 1,609 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you