1. LEHIN aiye buburu yi,
Aiye ekun on osi yi,
Ibi rere kan wa,
Ayipada ko si nibe?
Ko s’ oru, af’ osan titi,
Wi mi, ‘wo o wa nibe?
2. ‘Lekun ogo re ti m’ ese,
Ohun eri ko le wo ‘be
Lati b’ ewa re je,
L’ ebute daradara ni,
A ko ni gburo egun mo,
Wi mi, ‘wo o wa nibe?
3. Tan’ y’o de be? Onirele
T’o f’ iberu sin Oluwa,
T’ nwon ko nani aiye:
Awon t’ a f’ Emi Mimo to,
Awon t’o nrin l’ ona toro,
Awon ni o wa bibe.
(Visited 3,734 times, 6 visits today)