1. NINU gbogbo ewu oru,
Oluwa l’ O nso wa;
A wa tun ri imole yi,
A tun tee kun ba.
2. Oluwa pa wa mo loni,
Fi apa Re so wa,
Kiki awon t’ Iwo pamo,
L’o nyo ninu ewu.
3. K’ oro wa ati iwa wa
Wipe, tire l’ awa;
Tobe k’ imole otito
Le tan l’ oju aiye.
4. Ma je k’ a pade lodo Re,
Olugbala owon:
Titi a o f’ oju wa ri
Oju Re nikehin.
(Visited 3,551 times, 1 visits today)