1. TAL’ o mo adun isimi,
B’ o ye l’ awon t’ o ni,
Ti se ‘pin awon ayanfe,
Nipa eje Jesu?
2. Tal’ o le so ‘jinle ayo,
T’ o nsun li okan won,
Lat’ orisun oro Jesu,
Ati ileri Re?
3. Nwon n’ itelorun ‘dariji,
Nwon mo ‘po won daju;
‘Banuje ati ayida,
Ko le ru ‘simi won.
4. Ese ko le se ‘fisun won;
Kristi Onidajo
Ti da won n’de nipa ‘ku Re
Lori agbelebu.
5. Eru iku ko le ba won,
Nwon ti gba iye na;
Nwon bo lowo ‘dajo t’ o mbo,
Nipa ‘dalare Krist’.
6. A! k’ eyi ‘pin mi, Jesu,
Se mi l’ ayanfe Re,
‘Gbana mo d’ alabukunfun
At’ elekun ayo.
(Visited 60 times, 1 visits today)