1. KINI gbogbo lala Re
L’ ori mi fun, Jesu,
At’ anfani t’ O fun mi
Ju awon miran lo?
‘Gbat’ opo nrin n’nu ‘foju,
T’ O fun mi ni ‘laju,
T’ O le ‘yemeji mi lo,
Jesu, eredi re?
2. Ese ti O fi fa mi
S’ imo asiri Re?
Ohun t’ o sokun f’ aiye
T’ O sipaya fun mi?
Kil’ o jek’ O wi fun mi
P’ a ti dariji mi
Lai ti fi aiye sile?
Jesu, kil’ ohun na?
3. Nigbati mba ronu re,
Mo ha le sai bere
Ohun t’ o jek’ O yan mi,
Otosi elese?
Kini, Oluwa, kini
Mu k’ O feran mi be?
Imo nla t’ o fe ‘tumo,
Oluwa, wi fun mi.
4. Ife Baba l’ ori mi
Lati aiyeraiye,
N’ itumo Emi Mimo
S’ ibere ‘yanu yi;
O fe mi k’ a to bi mi,
Ki nto mo pen go fe,
O f’ ara da ese mi
Lati se mi l’ ogo.
(Visited 192 times, 1 visits today)