YBH 57

MIMO, mimo, mimo! Olodumare!

1. MIMO, mimo, mimo! Olodumare!
Ni kutukutu n’Iwo o gbo orin wa;
Mimo, mimo, mimo! Oniyonu julo!
Ologo meta lai, Olubukun!

2. Mimo, mimo, mimo! Awon ti orun nyin
Nwon nfi ade wura won lele y’ ite ka:
Kerubim, Serafim nwole niwaju Re,
‘Wo t’ O ti wa t’ O si wa titi lai.

3. Mimo, mimo, mimo! B’ okunkun pa O mo,
Bi oju elese ko le ri ogo Re;
Iwo nikan l’ O mo, ko tun si elomi,
Pipe n’nu agbara ati n’ ife.

4. Mimo, mimo mimo! Olodumare!
Gbogbo ise Re n’ ile l’ oke l’ o nyin O;
Mimo, mimo, mimo! Oniyonu julo!
Ologo meta lai, Olubukun!

(Visited 8,590 times, 6 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you