1. MO fe iyera s’ apakan
Kuro l’ ero t’ aiye,
Ki nf’ akoko iwo orun
Kunle gba adura.
2. Mo few a nikan ki nsokun
Ti irobinuje,
N’ iyewu kin ran Olorun
L’ eti ileri Re.
3. Mo fe ro anu t’o koja,
Be fun ore ti mbo,
Ki nko edun mi le ori
Eniti mo juba.
4. Mo fe ma fi igbagbo wo
Ohun didan t’ orun,
Ireti won fun mi l’okun
Larin iji aiye.
5. Nigba lala aiye ba pin,
Ki wiwo re le jo
Akoko yi n’ iparoro,
K’ aiyeraiye bere.
(Visited 445 times, 1 visits today)