YBH 571

OLUWA, iji nfe s’ oke

1. OLUWA, iji nfe s’ oke!
Igbi omi nru s’ oke!
Oju orun pelu su dudu,
‘Ranlowo ko si n’ tosi;
‘Wo ko bere bi a segbe?
Ba o n’ Iwo se le sun?
Gbati ‘seju kokan d’ eru ba wa
Pe omi n’ iboji wa.
Afefe at igbi yo se ‘fe Mi; Dake je!
Ibase ibinu riru okun,
Ibase esu tab’ ohunkohun,
Ko si omi t’ o le ri oko na,
Ti Oluwa orun at’ aiye wa,
Nwon yio f’ inudidun se ‘fe Mi, Dake je!
Dake je!
Nwon yio f’ inudidun se ‘fe Mi, Dake je!

2. Oluwa pel’ edun emi mi,
Mo teriba n’ ironu,
Inu okan mi ko n’ isimi;
A! ji k’ O gba mi, mo be!
Igba ese on ‘banuje,
Ti b’ okan mi mole;
Mo segbe! Oluwa, mo segbe!
A, yara k’ O si gba mi.

3. luwa, eru ti koja,
Idakeje si ti de,
Orun f’ oju han nin’ adagun,
Orun si wa l’ aiya mi;
Ma duro, Olurapada,
Ma fi mi sile mo;
Pel’ ayo ngo d’ ebute ibukun,
Ngo simi l’ ebute na,

(Visited 1,515 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you