1. JEJE, lai si ariwo,
Jeje li orun nran,
Gbat’ o bay o n’ ila re,
Eda le w’ oju re;
B’ o si ti ngoke pele,
Je l’ agbara re npo,
Titi y’o fi kan ‘tari
N’n’ ogo t’ a ko le wo.
2. Kokoro ‘yun n’nu okun,
Ko s’ en t’ o gbo ‘gbe re;
Kele l’ o nsa ‘hun elo
Ti o fi nsise re;
Lai ago, lai p’ okiki,
L’ o mu ‘se re yori;
Ise re l’ ewa tobe
T’ enia nfi s’ oso.
3. Okunkun t’ o n’ ipa ju
Ko wa pelu iro;
Iji nla t’ o si now ‘le
Ti f’ ategun jeje,
Bayi n’ is’ Emi Mimo
Li okan elese,
Lai lu ‘lu, lai fon fere,
L’ O so wa di mimo.
4. Jesu, jek’ is’ ore wa,
Lo pelu ipamo,
K’ a ma jek’ ow’ otun wa
Mo ebo t’ osi nru;
Laipe, nigbat’ o ba se
Ao ri b’ ohun elo
Ti Angeli ti so di
Ade ogo fun wa.
(Visited 397 times, 1 visits today)