1. EREDI iwa s’ aiye mi?
‘Tori kil’ a bi mi?
Gbogb’ ohun l’ aiye l’ o n’ idi,
Kil’ a ha da mi fun?
2. Ninu gbogbo ohun t’ a da,
Enia l’ o ga ju;
O ga l’ ero, l’ oye, l’ ogbon,
Li anfani gbogbo.
3. Idagba han l’ otun, l’ osi,
Ko s’ ohun t’ o duro;
A! okan mi ki ha se fun
Idagba l’ a da o?
4. Isise aiye mi poju,
Mo y’ arara l’ emi,
Op’ odun ko je mi l’ ere,
Mo si wa bakanna.
5. Ji mi ninu ijafara,
Emi Mimo, ji mi,
Fi onje ti orun bo mi,
Ki nle dagba l’ emi.
(Visited 434 times, 1 visits today)