1. A JESU, Iwo nduro
Lode, lehin ‘lekun,
Iwo fi suru duro
Lati koja s’ ile;
‘Tiju ni fun wa, Kristian’,
Awa ti nj’ oko Re!
Itiju gidigidi!
B’ a ba jo Re sode.
2. A Jesu, Iwo nkankun
Owo na si l’ apa,
Egun yi ori Re ka,
Ekun b’ oju Re je,
A! Ife ‘yanu l’ eyi
T’ O nfi suru duro!
A! Ese ti ko l’ egbe
T’ o ha ‘lekun pinpin!
3. A Jesu, Iwo mbebe
L’ ohun pelepele,
“Mo ku f’ eyin omo Mi
Bayi l’ e se Mi si?”
Oluwa, a s’ ilekun
N’ ikanu on ‘tiju!
Olugbala wa wo ‘le
Ma fi wa sile lo.
(Visited 754 times, 3 visits today)