1. JESU ma to wa
Tit’ ao fi simi;
Bi ona wa ko tile dan,
A o tele O l’ aifoya;
F’ owo Re to wa
S’ ilu Baba wa.
2. B’ ona ba l’ewu,
B’ ota sunmo wa,
Ma je k’ aigbagbo m’ eru wa,
Ki ‘gbagbo on ‘reti ma ye;
Tor’ arin ota
L’ a nlo s’ ile wa.
3. Gbat’ a fe ‘tunu
Ninu ‘banuje,
Gbati ‘danwo titun ba de,
Oluwa fun wa ni suru;
F’ ilu ni han wa
Ti ekun ko si.
Stanza 4 of Hymn 585
Jesu ma to wa
Tit’ ao fi simi,
Amona orun toju wa,
Dabobo wa, tu wa ninu,
Titi ao fi de,
Ilu Baba wa.
(Visited 585 times, 1 visits today)