1. OLORUN emi wa, at’ igbala wa,
‘Mole okunkun wa, ‘reti ile wa,
Gbo, ki O si gba ebe ijo Re yi,
Olodumare.
2. Wo bi ibinu ti yi Arki Re ka,
Wo b’ awon ota Re ti nt’ asia won,
Bi nwon si ti nju ida oloro won;
‘Wo le pa wa mo.
3. ‘Wo le se ‘ranwo, b’ iranwo aiye ye,
‘Wo le gba nib a b’oku ese gbija;
Iku at’ egbe ko le bor’ Ijo Re;
F’ alafia fun wa.
4. Ran wa lowo tit’ ota o pehinda,
K’ awon ‘loto Re ki nwon ni ‘dariji,
K’ a r’ alafia l’ aiye, lehin ija wa,
Alafia l’ orun.
(Visited 397 times, 1 visits today)