1. NINU oru ibanuje,
L’ awon egbe ero ayo,
Nwon nkorin ‘reti at’ ayo,
Nwon nlo s’ ile ileri.
2. Niwaju wa nin’ okunkun,
Ni imole didan ntan,
Awon arakunrin nsape,
Nwon nrin lo li aifoya.
3. Okan ni imole orun,
Ti ntan s’ ara enia Re;
Ti nle gbogbo eru jina,
Ti ntan yi ona wa ka.
4. Okan ni iro ajo wa,
Okan ni igbagbowa,
Okan l’ enit’ a gbekele,
Okan ni ireti wa.
5. Okan l’ orin t’ egberun nko,
Bi lati okan kan wa;
Okan n’ ija, okan l’ ewu,
Okan ni irin orun.
6. Okan ni inu didun wa,
L’ ebute ainipekun;
Nibiti Baba wa orun,
Y’o ma joba titi lai.
7. Nje k’ a ma nso arakunrin,
T’ awa ti agbelebu;
E je k’ a ru ki a jiya
Tit’ a o fi ri ‘simi.
8. Ajinde nla fere de na,
‘Boji fere si sile,
Gbogb’ okun wa y’o si tuka,
Gbogbo ‘se wa y’o si tan.
(Visited 506 times, 1 visits today)