YBH 580

JESU fe mi, emi mo

1. JESU fe mi, emi mo;
Bibeli so fun mi be;
Tire l’ awon omode,
Nwon ko l’ agbara, On ni.

2. Jesu fe mi, O ti ku
Lati si orun sile;
Yio we ese mi nu,
Y’o je k’ omo Re wo ‘le.

3. Jesu fe mi, O fe mi,
Be emi tile s’ aisan,
Lor’ akete arun mi,
O t’ ite Re wa so mi.

4. Jesu fe mi, yio duro
Ti mi l’ ona mi gbogbo;
Bi mo ba fe, ti mo ku,
Yio mu mi re ‘le orun.

 

 

(Visited 2,167 times, 4 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you