1. KO to k’ awon mimo beru,
Ki nwon so ‘reti nu;
‘Gba nwon ko reti ‘ranwo Re,
Olugbala yio de.
2. Nigbati Abram mu obe,
Olorun ni, “Duro;”
Agbo ti o wa lohun ni
Y’o dipo omo na.”
3. Gba Jona ri sinu omi,
Ko ro lati yo mo;
Sugbon Olorun ran eja
T’ o gbe lo s’ ebute.
4. B’ iru ipa at’ ife yi
Ti po l’ oro Re to!
Emi ba ma k’ aniyan mi
Le Oluwa lowo!
5. E duro de iranwo Re,
B’ o tile pe, duro;
B’ ileri na tile fa ‘le
Sugbon ko le pe de.
(Visited 10,330 times, 1 visits today)