YBH 578

ONISEGUN nla wa nihin

1. ONISEGUN nla wa nihin,
Jesu abanidaro;
Oro Re mu ni l’ ara da,
A, gbo ohun ti Jesu!
Iro didun l’ orin Seraf’,
Oruko didun li ahon,
Orin t’ o dun julo ni,
Jesu! Jesu! Jesu!

2. A fi gbogb’ ese re ji o;
A! gbo ohun ti Jesu!
Rin lo s’ orun l’alafia,
Si ba Jesu de ade.

3. Gbogb’ ogo fun Krist’ t’ O jinde!
Mo gbagbo nisisiyi;
Mo f’ oruko Olugbala,
Mo fe oruko Jesu.

4. Oruko Re l’ eru mi lo;
Ko si oruko miran;
B’ okan mi ti nfe lati gbo
Oruko Re ‘yebiye.

5. Arakunrin, e ba mi yin,
A, yin oruko Jesu!
Arabirin, gb’ ohun s’ oke,
A, yin oruko Jesu!

6. Omode at’ agbalagba,
T’ o fe oruko Jesu,
Le gba ‘pe ‘fe nisisiyi,
Lati sise fun Jesu.

7. Nigbat’ a ba si de orun,
Ti a ba si ri Jesu,
Ao ko ‘rin y’ ite ife ka,
Orin oruko Jesu.

(Visited 3,301 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you