YBH 577

ORE-OFE! Ohun

1. ORE-OFE! Ohun
Adun ni l’ eti wa;
Gbongbon re yio gba orun kan,
Aiye o gbo pelu.
Ore-ofe sa,
N’ igbekele mi;
Jesu-ku fun araiye,
O ku fun mi pelu.

2. Ore-ofe l’ o ko
Oruko mi l’ orun;
L’ o fi mi Od’-agutan,
T’ O gba iya mi je.

3.Ore-ofe to mi
S’ ona alafia;
O ntoju mi l’ ojojumo,
Ni irin ajo mi.

4. Ore-ofe ko mi
Bi a ti gb’ adura;
O pa mi mo titi d’ oni,
Ko si jeki nsako

5. Je k’ ore-ofe yi,
F’ agbara f’ okan mi;
Ki nle fi gbogbo ipa mi
At’ ojo mi fun O.

(Visited 5,424 times, 11 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you