1. L’ AYO l’ a ro t’ ore-ofe
Alufa wa l’ oke;
Okan Re kun fun iyonu,
Aiya Re ntan fun ‘fe.
2. Nipa ibakedun okan,
O mo ailera wa;
O mo ohun t’ idanwo je,
Nitor’ O ti ri ri.
3. Li ojo ailera ara,
O ke, O si sokun,
N’ iwon ti Re O mo l’ otun
Eru awon Tire.
4. Je ki a fi igbagbo be
F’ anu at’ ipa Re;
Ao ri ore igbala gba
N’ igba ‘ponju gbogbo.
(Visited 596 times, 1 visits today)