YBH 575

FUN mi n’ iwa pele

1. FUN mi n’ iwa pele,
Okan tutu;
Ifarabale bi
T’ Oluwa mi;
Irele on suru
At’ opo oiyonu,
Ninu ohun gbogbo
Ki njo Jesu.

2. Fun mi n’ itelorun
N’ ipo k’ ipo;
Ko le re ‘le ju yi
T’ a bi Jesu.
Fun mi n’ itunu Re.
At’iranlowo Re
Ninu ohun gbogbo
Ki njo Jesu.

3. Fun mi ni itara
S’ ipa Tire;
Aniyan at’ ife
S’ ohun t’ orun;
Fun mi n’ iwa mimo,
Ikorira ese,
Ninu ohun gbogbo
Ki njo Jesu.

4. Fun mi ni igbagbo
At’ ireti;
Fun mi l’ ayo ‘gbala
Ninu Jesu;
F’ emi iye fun mi,
Fun mi l’ ade ogo,
‘Gbati mo ba jinde
Ki njo Jesu.

(Visited 4,095 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you