YBH 574

LAB’ agbelebu Jesu

1. LAB’ agbelebu Jesu
Mo fe lati duro, –
Oji apata titobi
Ninu ile are,
Ibugbe ninu aginju,
Ib’ isimi l’ ona,
Kuro n’n’ oru osangangan,
Pelu wahal’ ojo.

2. Abo ayo t’ o daju,
Ib’ isadi t’ o dun,
Ibit’ ayo lati orun
At’ idajo pade
Gege bi a ti ala
Han Jakob’ nigbani,
Bel’ agbelebu ri fun mi,
Akaso si orun.

Stanza 3 of Hymn 574

Sugbon ni apa keji,
Labe ojiji re,
Ni iboji t’ o sokun wa
T’ o si yanu sile;
Nibe li agbelebu wa
T’ o na ‘wo igbala,
B’ oluso t’ a yan lat’ to mi
Kuro l’ ona egbe.

Stanza 4 of Hymn 574

Lor’ agbelebu Jesu
Oju mi le ma ri
Enit’ O jiya, t’ O npoka
Iku nibe fun mi,
Mo jew’ ohun ‘yanu meji
Lati okan t’ o gb’ ogbe,
Iyanu t’ ife ogo Re,
Ati alaiye mi.

5. Agbelebu, mo f’ oji re,
Se ib’ isimi mi,
Nko bere imole miran
Ju ‘mole oju Re;
O te mi l’ orun k’ aiye lo
Ki nma mo ere kan,
Ara se itiju mi,
Agbelebu l’ ogo mi.

(Visited 497 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you