1. ENIKAN mbe t’ O feran wa,
A! O fe wa!
Ife Re ju t’ iyekan lo,
A! O fe wa!
Ore aiye nko wa sile,
B’ oni dun, ola le koro,
Sugbon Ore yi ko ntan ni,
A! O fe wa!
2. Iye ni fun wa b’ a ba mo,
A! O fe wa!
Ro, b’ a ti je ni ‘gbese to,
A! O fe wa!
Eje Re l’ O si fir a wa,
Nin’ aginju l’ O wa wa ri,
O si mu wa wa s’ agbo Re.
A! O fe wa!
3. Ore ododo ni Jesu,
A! O fe wa!
O fe lati ma bukun wa,
A! O fe wa!
Okan wa fe gbo ohun Re
Okan wa fe lati sunmo,
On na ko si ni tan, wa je,
A! O fe wa!
4. On l’ O jek’ a r’ idariji,
A! o fe wa!
On O le otawa sehin,
A! O fe wa!
On O pese ‘bukun fun wa,
Ire l’ a o ma ri titi,
On O fi mu wa lo s’ ogo,
A! O fe wa!
(Visited 4,558 times, 5 visits today)